Adekunle Gold | |
---|---|
Orúkọ àbísọ | Adekunle Kosoko |
Ọjọ́ìbí | 28 Oṣù Kínní 1987 Lagos State |
Irú orin | |
Occupation(s) |
|
Instruments | |
Years active | 2010–present |
Associated acts | |
Website | adekunlegold.com |
Adekunle Almoruf Kosoko (tí a bí ní Oṣù Kìíní Ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, Ọdún 1987), tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Adekunle Gold àti AG Baby, jẹ́ olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, akọrin sílẹ̀ ati ayàwòrán. [1] Ó di ìlúmọ̀ọ́ká olórin lẹ́yìn tí ó kọ orin kan tí a mọ̀ sí “Ṣadé” ní ọdún 2015. Ní ọdún 2015, ó fọwọ́síwèé àdéhùn ìgbàsílẹ̀ pẹ̀lú YBNL Nation tí ó sì gbé orin [[studio]] kan jáde tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Gold, èyí tí ó wà ní ipò keje ti Billboard àgbáyé. Ṣáájú Gold ni ó ti kọ àwọn orin mẹ́ta kan tí àkọ́lé wọn ń jẹ́ "Sade", "Orente" ati "pick up". Adekunle Gold fi hàn sí Ilé Ìdanilárayá Nàìjíríà lónìí pé ṣáájú kí ó tó f'ọwọ́ sí pẹ̀lú YBNL, ó ṣe àpẹẹrẹ aami ti ilé-iṣẹ́ náà àti pé ó parí àwọn àpẹẹrẹ mìíràn fún Lil Kesh, Viktoh àti Olamide.[2]