Attahiru Jega | |
---|---|
![]() Jega ń sọ̀rọ̀ ní Chatham House ní oṣù kẹta ọdun 2016 | |
Alága kẹrin aájò elétò Independent National Electoral Commission | |
In office 8 June 2010 – 31 June 2015 | |
Asíwájú | Maurice Iwu |
Arọ́pò | Amina Zakari |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Attahiru Muhammadu Jega 11 Oṣù Kínní 1957 Jega, Northern Region, British Nigeria (now in Kebbi State, Nigeria) |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Attahiru Muhammadu Jega (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kínní ọdún 1957) jé Ọ̀mọ̀wé àti gíwá àná Yunifásítì Báyéró tí ìpínlè Kano tẹ́lẹ̀rí.[1] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdun 2010, ààrẹ Goodluck Jonathan yan(pẹ̀lú ìfọwọsí ilé ìgbìmò asòfin) gẹ́gẹ́ bi alága Independent National Electoral Commission (INEC), ajo tí ó ń rí si ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, ààrẹ yan, àwọn ilé ìgbìmò asofin sì fi owó si yíyàn rẹ̀ láti rọ́pò Ọ̀jọ̀gbọ́n Maurice Iwu, ẹni tí ó fi ipò náà lè ní ọjọ́ kejìdínlógbọ̀n oṣù kẹrin ọdun 2010.[2] Jega nìkan ni alága ààjọ INEC tí ó se àmójútó ìdìbò Nàìjíríà méjì (ọdun 2011 àti ọdun 2015). Jega fi ipò náà kalẹ̀ ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 2015, ó fi ipò náà lé Amina Zakari gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Muhammadu Buhari se pá láṣẹ fun.[3]