Type | Private |
---|---|
Founded | 1981 |
Founder(s) | Aliko Dangote |
Key people | Aliko Dangote (President & CEO) |
Industry | Conglomerate |
Products | |
Revenue | ▲ US$4.1 billion (2017)[1] |
Employees | 30,000 |
Website | dangote.com |
Ilé-iṣẹ́ alájọni Dangote ni orúkọ àkójọpọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ tí àkójọpọ̀ oníṣòwò àti ẹni tí ó lówó jùlọ nílẹ̀ Áfíríkà, Alhaji Aliko Dangote dá sílẹ̀ káàkiri àgbáyé àti lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà . Ó jẹ́ ìgbìmọ̀ ìjọba tó tóbi jùlọ ní Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà àti ọ̀kan nínú àwọn tó tóbi jùlọ ní ilẹ̀ Áfíríkà . Ẹgbẹ́ náà ń gba òṣìṣẹ́ tó ju ènìyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n lọ tó sì pa tó owó US $ 4.1 billion US ni ọdun 2017.
Ilé-iṣẹ́ náà di dídásílẹ̀ ní ọdún 1981 bí ile-iṣẹ ìṣòwò,tó ń gbé ṣúgà, sìmẹ́ǹtì, ìresì, ẹja àti àwọn ọjà oúnjẹ mìíràn wọlé láti òkèèrè fún títà káàkiri ọjà Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ láti máa ṣe sìmẹ́ǹtì ní ọdún 1990, lẹ́yìn náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe aṣọ,ṣíṣe àkàrà ìyẹ̀fun, ṣíṣe iyọ̀ ati ìsọdọ̀tun ṣúgà ní ìparí ọdún mẹ́wàá si. Ilé-iṣẹ́ náà tún yípadà sí ìṣèlọ́pọ sìmẹ́ǹtì,ó sì gbòòrò kíákíá dé àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà mìíràn. Àti máa jẹ́ òǹtajà kan ṣoṣo lọ́jà jẹ àmì ìṣàfihàn ìsọdọmọ Ilé-iṣẹ́ alájọní Dangote.
Ẹgbẹ́ náà báyìí, ní ilé- iṣẹ́ àdáni àti alájọní méjìdínlógún, tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà mẹwàá. Dangote Cement, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ilé-iṣẹ́ alájọní tó wà lára Ètò ìṣura Pàṣípàrọ̀ ti Ìlú Nàìjíríà,tí owó ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọjà wọn sì jẹ́ bíi ìpín ogún ti owó gbogbo Ètò Ìṣura Pàṣípàrọ̀ Ìlú Nàìjíríà . Ilé-iṣẹ́ gbogbogbò Dangote wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó.
Ní ọdún 2016, Dangote fọwọ́ sí ìwé àdéhùn pẹlú ẹgbẹ́ CNOOC láti fi òpó epo rọ̀bì ńlá sí abẹ́ omi. Nígbà tí wón bá parí ṣíṣe òpò epo rọ̀bì náà, yóò fààgùn lati Bonny ( Ìpínlẹ̀ Rivers ) lọ́nà Ògèdèǹgbé,Olokola sí Lekki ati ibi òpó epo Escravos ti Èkó, yóò sì parí sí Òpópónà òpó epo rọ̀bì ti Àpapọ̀ Ìwọ̀ o Oòrùn Ilẹ̀ Áfíríkà. [2]