Derek William Bentley (30 Osu kefa Ọdun 1933 – 28 Oṣu Kini Ọdun 1953) jẹ ọkunrin ara ilu Gẹẹsi kan ti a pa nipa siso o ro titi emi fi bo ni enu re fun ipaniyan ọlọpa kan lakoko igbiyanju idigun jale kan. Christopher Craig, ẹni ọdun mokan din l'ogun ti o je ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ Bentley, ni a fi ẹsun ipaniyan naa kan. Bentley fi idi re mule wipe Bentley jẹbi ẹsun kikopa ninu itapa si ofin naa, nipasẹ ilana ofin kan ninu iwe ofin ile Gẹẹsi ti a mo si “ ifọwọsowọpọ ”, nitori wipe iwa idigun jale yi ni a se pelu isokan. Idajo naa ko wa ni isokan.
Awọn igbimo idajo ti a gbe kale fi idi re mule wipe Bentley jẹbi esun ti a fi kann lori itumo ti agbejoro ijoba fun oro kan ti Bentley so wipe "Jẹ ki o gbaa" (iyanju ti Bentley fun Craig), ti a ko si le fi itumo re lele ni pato tabi idaniloju leyin ti onidajọ.Oloye Goddard, ti ṣe apejuwe Bentley gẹgẹbi "eni ti o se iranlọwọ ọpọlọ ninu ipaniyan Sidney Miles".Goddard ṣe idajọ iku fun Bentley nipa siso ro titi ti emi yi o fi bo ni enu re lai bikita fun idirebe awon igbimo idajo lati dari ji arakunrin naa: Labẹ Idajọ ti Ofin Iku 1823, ko si idajo miiran ti o ṣee ṣe (biotilejepe Ofin ipaniyan 1957, eyiti o ṣafihan awọn aabo ojuse ti o din(biotilejepe Ofin ipaniyan 1957, eyiti o ṣafihan awọn aabo ojuse ti o dinku ti o lagbara, ti fẹrẹẹ jẹ ipa nipasẹ ejo Bentley yi).
Ẹjọ Bentley yi di mimo kaakiri ilu ti o fi je wipe o yori si ipolongo ọdun marun din laadota lati gba idariji fun Derek Bentley lẹhin iku re, eyiti o di sise ni ọdun 1993, pelu ipolongo lati pa ejo iku ti pa ejo iku ti a da fun rẹ, eyiti o waye ni ọdun 1998. Nitoribẹẹ ọran rẹ yi ni a ka si ọran ti ilodi si idajọ pelu ejo ti Timothy Evans, eyi ti o si je idi kan pataki ninu aṣeyọri ipolongo lati fopin si ijiya iku ni ile Geesi .