Àdàkọ:Infobox Education Ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ó wà ní abẹ̀ ̀akóso aj̀ọ tí ó ń rísí ètò-èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti a mọ sí Federal Ministry of Education.[1] Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń ṣe ìmúṣẹ àgbékalẹ̀ ìlànà ètò-ẹ̀kó tí ìjọba ìpínlẹ̀ wọn bá gbé kalẹ̀ fún lílò ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ àti ti gbogbo-gbòò .[2] Ìlànà ìkọ́ni ní orílè-èdè Nàìjíríà pín sí ọ̀nà mẹ́ta. Àkọ́kọ́ ni ilé-ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmin, èkejì ni ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ẹ̀kẹta ni ilé-ẹ̀kọ́ girama, nígbà tí ẹ̀kẹrin jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ àgbà.[3] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìjọba ni ó ń ṣ'àkóso ètò ẹ̀kọ́, àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba gbogbo ni wọn kò fi bẹ́ẹ̀ dúró ṣinṣin láti ìgbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti gba òmìnira kúrò lọ́wọ̀ àwọn gẹ̀ẹ́sì bìrìtìkó, síbẹ̀, ètò ẹ̀kọ́ kárí-ayé tí ò gúnmọ́ kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ìgbà náà wá.[4] Oríṣiríṣi ìyàtọ̀ ni ó wà nìnú ìlànà àtẹ ètò-ẹ̀kọ́, tí owó níná sì ètò ẹ̀kọ́ náà sì tún ń ṣ'àkóóbá fun pẹ̀lú.[5][6] Lọwọlọwọ bayi, orilẹ-eded Naigiria ni o ni awọn ọmọ ti wọn ko si ni ile-ẹkọ julọ ni orile agbaye.[6] Oríṣi ilé-ẹ̀kọ́ méjì ni ó wà ní orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà, àkọ́kọ́ ni ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba, èkejì ni ilé ẹ̀kọ́ aládàáni [7] Ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n ma ń fi èdè gẹ̀ẹ́sì ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, ní ọgbọ̀nọjọ́ oṣù kọkànlá ọdún 2022 ni mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, ọ̀gbẹ́ni Adamu Adamu kéde wípe ìjọba ń gbèrò láti dẹ́kun lílo èdè gẹ̀ẹ́sì fún ìgbèkọ́ ní àwọn ilé-èkọ́ aĺakọ̀ọ́bẹ̀rẹ ̀gbogbo kí wọ́n sì fi èdè abínibí tí wón bá ń ṣàmúlò rẹ̀ ní agbègbè tí ilé-ẹ̀kọ́ náà bá wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjírìà.[8]