Queen's College, Lagos, jẹ́ ilé-ìwé gírámà Ìjọba tí ó wà fún àwọn Obìnrin nìkàn. Ilé-ìwé yìí wà ni Yàbá, ìpínlè Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì ní àwọn ohun èlò ibùgbé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ọjọ́ kẹwàá, oṣù ọ̀wàwà, ọdún 1927, nígbà tí Nàìjíríà ṣì wà lábẹ̀ àwọn òyìnbò amúnisì ni a dá ilé-ìwé yìí sílẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn sì mọ̀ ọ́ sí “ilé-ìwé àwọn Obìnrin ti King's College, Lagos”.[1]
Nàìjíríà ní ètò ẹ̀kọ́ ọ́ 6-3-3-4. Ilé-ìwé Queen's College máa ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama ní ìpele méjì tí ó wà láàárín. Àwọn ọ̀wọ́ ọlọ́dún mẹ́fà, tàbí ìpele ọlọ́dún mẹ́fà wà; ọ̀wọ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan ní tó ẹgbẹ̀ta akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n tún pín sí ìsọ̀rí lóríṣiríṣi. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ààyè ìyàrá-ìkàwé wọn ti dínkù sí ohun tí kò lè gbà ju akẹ́kọ̀ọ́ ogójì lọ. Ní sáà 2006/2007, àpapọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà ní ilé ìwé yìí ni ọgọ́jọ-lé-ẹgbàá.
Ẹ̀méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ilé ìwé yìí ti ní èsì ìdáwò tí ó tayọ àwọn elegbé rẹ̀ nínú ìdánwò àṣekágbá oní ìwé kẹwàá láti ọdún 1985 tí àjọ (WASSCE) West African Examination Council ṣe agbátẹrù rẹ̀. Fún ìdí èyí, wọ́n wà lára àwọn ilé-ìwé tó ṣe gbòógì ní orílè-èdè Nàìjíríà, àti ní ilè Áfíríkà lápapọ̀. Akọmọ̀nà ilé-ìwé Queen's College ni "Pass On The Torch". Ohun tí ó jẹ ilé-ìwé yìí lógún ni fífún obìrin àti ọmọ obìrin ní ẹ̀kọ́ tó yèporo. Àfojúsù wọn ni " produce generation of women who will excel, compete globally and contribute meaningfully to nation building" ṣíṣe ìgbéǹde àwọn obìrin tí wọn tayọ, tí wọn lè fi igagbaga lágbàáyé, tí wọ́n sì lè ṣe oun tí ó ni ìtumọ̀ ní àwùjọ