Rachel Baard

Rachel Sophia Baard jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ó ẹ̀sìn ti orílẹ̀-èdè South African. Láti ọdún 2019, ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti Theology and Ethics ní Union Theological Seminary ní Richmond, Virginia, United States.[1][2] Ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn Sexism and Sin-Talk: Feminist Conversations on the Human Condition (2019) gba àmì-ẹ̀yẹ ti 2020 Andrew Murray / Desmond Tutu Book Prize.[2] Àwọn iṣé-ìwádìí rẹ̀ dá lórí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ẹ̀kọ́ ìwà ajẹmẹ́sìn, ìṣègbèfábo àti ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ajẹmọ́-ìṣèlú.[3]

Ilé-ẹ̀kọ́ Stellenbosch University ni ó ti jáde, pẹ̀lú oyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ òfin àti ẹ̀kọ́ ìwà ajẹmẹ́sìn. Ó gba oyè Ph.D. ti ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láti Princeton Theological Seminary. Lẹ́yìn náà ni ó lọ sí Richmond, ní kété tí ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Villanova University.[2][3]

  1. "Union Presbyterian Seminary awarded $1 million grant to help faith leaders address the nation’s cultural divide". Presbyterian Mission Agency (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-01-11. Retrieved 2022-11-04. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Faculty: RACHEL S. BAARD". Union Presbyterian Seminary. 
  3. 3.0 3.1 "Author: Rachel Sophia Baard". Westminster John Knox Press. 2019-11-26. Retrieved 2022-11-04. 

From Wikipedia, the free encyclopedia · View on Wikipedia

Developed by Nelliwinne