Vaal Dam ni orílẹ̀-èdè South Africa ni a ṣe ní ọdún 1938 ó sì wà ní ìwọ̀n 77km gúúsù ti OR Tambo International Airport, Johannesburg . Adágún tí ó wà lẹ́hìn odi-ìdídò náa ní àgbègbè ojú tí ó fẹ̀ tó bíi 320 square kilometres (120 sq mi) [1] ó sì jìn ní ìwọ̀n mítà 47. Ìdídò Vaal wà lórí Odò Vaal, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òdò tí ńṣàn tí ó lágbára jùlọ ní orílẹ̀-èdè South Africa. Àwọn òdò mìíràn tí ńṣàn sínu ìdídò náà ni Odò Wilge,Odò Klip Molspruit ati Grootspruit.[2] Ó ní ju 800 kilometres (500 mi) ti etí òkun àti pé ó jẹ́ ìdídò ńlá kejì ti orílẹ̀-èdè South Africa nípasẹ̀ àgbègbè àti ẹ̀kẹrin tí ó tóbi jùlọ nípasẹ̀ ìwọ̀n.