Weekend Getaway | |
---|---|
Fáìlì:Weekend Getaway poster.jpg Theatrical release poster | |
Adarí | Desmond Elliot |
Olùgbékalẹ̀ |
|
Àwọn òṣèré | |
Olóòtú | Victor Ehi-Amedu |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Emem Isong Productions |
Olùpín |
|
Déètì àgbéjáde |
|
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | English |
Owó àrígbàwọlé | ₦22,895,273 (domestic gross)[2] |
Weekend Getaway jẹ́ fìímù ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jáde ní ọdún 2012. Desmond Elliot ni olùdarí fììmù àgbéléwò yìí, àwọn òṣèré tó kópa nínú rẹ̀ ni Genevieve Nnaji, Ramsey Nouah, Monalisa Chinda, Ini Edo, Uti Nwachukwu, Alex Ekubo, Bryan Okwara, Beverly Naya àti Uru Eke. Wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ mọ́kànlá, ó sí padà gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́rin nínú rè ní ayẹyẹ Nollywood & African Film Critics Awards (NAFCA), tí ọdún 2013[3][4]. Wọ́n sì tún yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ méjì ní 2013 Best of Nollywood Awards pẹ̀lú Alex Ekubo tó padà gba àmì-èyẹ fún òṣèrékùnrin tó dára jù lọ. Fíìmù yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí nípa ètò owó-iṣúná, nítorí àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó kópa nínú rẹ̀.[5]