Zina Saro-Wiwa | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1976 (ọmọ ọdún 48–49) Port Harcourt, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian, British |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Bristol |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 2008 - present |
Àwọn olùbátan |
|
Zina Saro-Wiwa (tí a bí ní ọdún 1976, Port Harcourt, Nigeria ) jẹ́ olórin fídíò àti onífíìmù tí ó gbé ní Brooklyn. Ó ṣe àwọn fídíò, àwọn ìwé àkọọ́lẹ̀, àwọn fídíò orin àti àwọn fíìmù àdánwò.
Saro-Wiwa ni olùdásílẹ fíìmù ti ẹgbẹ́ alt- Nollywood . Ìgbìyànjú tí ó ńlò ìtan-àkọọ́lẹ̀, àṣà àti àwọn àpéjọ wíwò ti ilé-iṣẹ́ fíìmù Nollywood ṣùgbọ́n fun awọn ajàfẹ́tọ-ènìyàn nípa ètò òṣèlú.
Ó jẹ́ akọ̀ròyìn BBC tẹ́lẹ̀ rí, a bí iṣé ọnà rẹ̀ jáde láti inú ìfẹ́ rẹ̀ láti mú ìyípadà bá ojú tí gbogbo àgbáyé fi ń wo Áfíríkà nípa lílo fíìmù, àwòrán, àti oúnjẹ. Iṣé rẹ̀ pẹ̀lú ni New West African Kitchen, iṣẹ́ àkànṣe kan níbi tí Saro-Wiwa ti ṣe àtúnrò nípa onjewiwa Iwọ-oorun Afirika . Ayẹyẹ kọ̀ọ̀kan tún ṣe àfihàn àwọn iflarahàn àwòrán fídíò Áfíríkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ kékeré kan.
Ní ọjọ́ kejìlólógún Oṣù Kẹta Ọdún 2011, Saro-Wiwa gba àmì ìdánimọ̀ gẹgẹ bí ọ̀kan nínú àwọn adarí mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ó ga jùlọ ti Renaissance Afirika nínú ìwé ìròyìn Times .[citation needed]